Skip to content
1 Kronika 23:28-32

1 Kronika 23:28-32

28
Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
29
Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òsùwọ̀n.
30
Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́.
31
Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.
32
Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options