Skip to content

Saamu93

OLÚWA Ń Jọba Títí Ayé

1
Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí.
2
Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé.

Agbára Ọlọ́run Lórí Ìkún

3
A ti gbé òkun sókè, Olúwa, òkun ti gbé ohùn wọn sókè; òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4
Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo.

Ìgbẹ́kẹ̀lé àti Ìwà Mímọ́

5
Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 90 chars

Options