Saamu84
Listen to this chapter
0:00
0:00
1
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
2
Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.
3
Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
4
Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ; wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
5
Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
6
Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.
7
Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.
8
Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára; tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
9
Wo asà wa, Ọlọ́run; fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ.
10
Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11
Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà; Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá; kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
12
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Options
Study Note