Saamu2
Listen to this chapter
0:00
0:00
1
Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
2
Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.
3
Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”
4
Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
5
Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀ yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
6
“Èmi ti fi ọba mi sí ipò lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”
7
Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa: Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí, èmi ti di baba rẹ.
8
Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
9
Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”
10
Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n; ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11
Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12
Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú, kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín, nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Options
Study Note