Saamu 150
Ibi àti Ìdí Tí A Fi Ń Yin Ọlọ́run 1–2
1
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀, ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
2
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
Àwọn ohun èlò orin àti gbogbo ohun tó mí yìn 3–6
3
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,
5
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè, ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.
6
Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Study note