Saamu125
Listen to this chapter
0:00
0:00
1
Orin fún ìgòkè. Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni, tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.
2
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3
Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
4
Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere, àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
5
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Options
Study Note