Saamu100
Listen to this chapter
0:00
0:00
1
Saamu. Fún ọpẹ́. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.
2
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa, ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
3
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀.
4
Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn; ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
5
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé; àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Options
Study Note