Saamu 92:7-15
7
nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé.
8
Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
9
Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká.
10
Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11
Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi.
12
Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,
13
tí a gbìn sí ilé Olúwa, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14
Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó, wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15
láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa; òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú kankan nínú rẹ̀.”
Settings