Skip to content
Saamu 89:19-37

Saamu 89:19-37

19
Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20
Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.
21
Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22
Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
23
Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.
24
Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25
Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun, àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá.
26
Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27
Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi, ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28
Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un, àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29
Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé, àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.
30
“Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀ tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
31
Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́ tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
32
nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò; àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;
33
ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
34
Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
35
Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra; èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
36
Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé, àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
37
A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá, àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run.” Sela.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options