Saamu 34:1-6
1
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2
Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa; jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3
Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4
Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5
Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n.
6
Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀; ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
Settings