Skip to content
Saamu 33:1-11

Saamu 33:1-11

1
Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo; ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
2
Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
3
Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.
4
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
5
Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.
6
Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
7
Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
8
Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
9
Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.
10
Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
11
Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 90 chars

Options