Skip to content
Saamu 20:1-5

Saamu 20:1-5

1
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
2
Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3
Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela.
4
Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
5
Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options