Saamu 119:33-40
33
Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34
Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35
Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36
Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37
Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38
Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára.
39
Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40
Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
Settings