Ń ṣàfihàn ẹsẹ 1 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi; ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2
Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
3
Okùn ikú yí mi ká, ìrora isà òkú wá sórí mi; ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4
Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa: “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”