Saamu 10:7-11
7
Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8
Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò. Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
9
Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10
Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11
Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé; Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
Settings