Òwe 2:1-9
1
Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
2
tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
3
àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
4
bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
5
Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
6
Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.
7
Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
8
Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
9
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
Settings