Lefitiku 16:20-28
20
“Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá.
21
Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà.
22
Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.
23
“Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.
24
Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.
25
Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ.
26
“Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó.
27
Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí Ibi Mímọ́ Jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà.
28
Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.
Settings