Skip to content
Lefitiku 1:1-5

Lefitiku 1:1-5

1
Olúwa sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé,
2
“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.
3
“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa
4
kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un.
5
Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options