Jeremiah 46:9-12
9
Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin, ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́. Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú, àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú; àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.
10
Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn, títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀. Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.
11
“Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti. Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn, kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
12
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ, igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé. Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ, àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”
Settings