Jeremiah 23:9-13
9
Nípa ti àwọn wòlíì èké. Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì. Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa; nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
10
Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn; nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ. Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.
11
“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run; kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni Olúwa wí.
12
“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni Olúwa wí.
13
“Láàrín àwọn wòlíì Samaria, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá. Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.
Settings