Jeremiah 2:33-37
33
Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ.
34
Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé. Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí
35
ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀; kò sì bínú sí mi.’ Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’
36
Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri láti yí ọ̀nà rẹ padà? Ejibiti yóò dójútì ọ́ gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria.
37
Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ, nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀, kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.
Settings