Jakọbu 2:14-19
14
Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí?
15
Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́,
16
tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́?
17
Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.
18
Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́.” Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi.
19
Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.
Settings