Isaiah 51:9-23
9
Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára ìwọ apá Olúwa; dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́. Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
10
Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí àti àwọn omi inú ọ̀gbun, tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
11
Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
12
“Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
13
tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
14
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ wọn kò ní kú sínú túbú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
15
Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
16
Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́, Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”
17
Jí, jí! Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu, ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa ago ìbínú rẹ̀, ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
18
Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́ kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.
19
Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú? Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
20
Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.
21
Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì.
22
Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́, “Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n; láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́.
23
Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”
Settings