Skip to content
Esekiẹli 32:24-32

Esekiẹli 32:24-32

24
“Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.
25
A ṣe ibùsùn fún un láàrín àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa.
26
“Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè.
27
Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè.
28
“Ìwọ náà, Farao, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàrín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.
29
“Edomu wà níbẹ̀, àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.
30
“Gbogbo àwọn ọmọ-aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sidoni wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.
31
“Farao, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ yóò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa Olódùmarè wí.
32
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Farao àti gbogbo ogun rẹ̀ ni a yóò tẹ́ sí àárín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options