Skip to content
Esekiẹli 30:13-16

Esekiẹli 30:13-16

13
“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run, Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi. Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.
14
Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro, èmi yóò fi iná sí Ṣoani, èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi.
15
Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu ìlú odi Ejibiti èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò.
16
Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti Pelusiumu yóò japoró ní ìrora. Ìjì líle yóò jà ní Tebesi Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options