Skip to content
Esekiẹli 24:3-14

Esekiẹli 24:3-14

3
Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná, gbé e ka iná kí o sì da omi sí i nínú.
4
Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀, gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá. Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀,
5
mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran. Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀; sì jẹ́ kí ó hó dáradára sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.
6
Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà, fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀! Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí má ṣe ṣà wọ́n mú.
7
“ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárín rẹ̀; à á sí orí àpáta kan lásán kò dà á sí orí ilẹ̀, níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó.
8
Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán, kí o ma bà á wà ni bíbò.
9
Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà! Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi.
10
Nítorí náà kó igi náà jọ sí i, kí o sì fi iná sí i. Ṣe ẹran náà dáradára, fi tùràrí dùn ún; kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná.
11
Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀ kí èérí rẹ̀ le jó dànù.
12
Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ: èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀, èérí náà gan an yóò wà nínú iná.
13
“ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.
14
“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options