Esekiẹli 15:1-5
1
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrín igi yòókù nínú igbó?
3
Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan tí ó wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́?
4
Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárín rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́?
5
Tí kò bá wúlò fún nǹkan kan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tí iná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín?
Settings