Eksodu 27:11-13
11
Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
12
“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.
13
Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.
Settings