Eksodu 27:10-15
10
pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú.
11
Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
12
“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.
13
Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.
14
Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
15
àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.
Settings