- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Ìpè Paulu àti ohun ìjìnlẹ̀ tí a ṣí payá
Efesu 3:1-13
Ìpè Paulu àti ohun ìjìnlẹ̀ tí a ṣí payá
1
Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.
2
Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín;
3
bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí.
4
Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi.
5
Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;
6
pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìyìnrere.
7
Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.
8
Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà;
9
àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi.
10
Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,
11
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa.
12
Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.
13
Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.
In this passage
- Who
- Where
- When
- About
See also
Where else Scripture says this.
Galatia 1:12
N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.from verse 32 Timotiu 1:9
ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé,from verse 9Efesu 2:18
Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.from verse 12Kolose 1:27
Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín.from verse 2Romu 16:25
Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,from verse 31 Kọrinti 15:9
Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn aposteli, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní aposteli, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run.from verse 8Romu 5:2
Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run.from verse 12Efesu 1:11
Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀,from verse 3Galatia 3:26
Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.from verse 6Galatia 3:29
Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.from verse 6Heberu 4:14
Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin.from verse 12Heberu 4:16
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.from verse 12
Study Note
Settings