Skip to content
Deuteronomi 18:15-22

Ìlérí wòlíì kan bí Mósè

Deuteronomi 18:15-22

Wòlíì kan bí Mósè

15
Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.
16
Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”
17
Olúwa sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára.
18
Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un.
19
Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
20
Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ní orúkọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú.”
21
Ṣùgbọ́n ìwọ lè wí ní ọkàn rẹ pé, “Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ?”
22
Nígbà tí ohun tí wòlíì bá sọ ní orúkọ Olúwa kò bá wá sí ìmúṣẹ tàbí jẹ́ òtítọ́, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ tí sọ láìwádìí. Kí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.

See also

Where else Scripture says this.

  • Ìṣe àwọn Aposteli 3:22

    Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín.
    from verse 15
  • Ìṣe àwọn Aposteli 3:23

    Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’
    from verse 15
  • Ìṣe àwọn Aposteli 7:37

    “Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’
    from verse 15
  • Johanu 1:45

    Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”
    from verse 15
  • Deuteronomi 18:15

    Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.
    from verse 18
  • Johanu 8:28

    Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ Ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi, ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí.
    from verse 18
  • Johanu 12:49

    Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí.
    from verse 18
  • Johanu 12:50

    Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀, nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”
    from verse 18
  • Heberu 1:1

    Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,
    from verse 15
  • Heberu 1:2

    ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
    from verse 15
  • Eksodu 20:19

    Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”
    from verse 16
  • Deuteronomi 18:18

    Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un.
    from verse 15
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options