Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 28:23-28

Ìṣe àwọn Aposteli 28:23-28

23
Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú Paulu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jesu láti inú òfin Mose àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.
24
Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́.
25
Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrín ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Paulu sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah wí pé:
26
“ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé, “Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.”
27
Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́, ojú wọn ni wọn sì ti di. Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́, àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’
28
“Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn kèfèrí wọ́n ó sì gbọ́!”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options