2 Ọba 4:21-27
21
Ó lọ sí òkè ó sì tẹ́ ọmọ náà lórí ibùsùn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì tìlẹ̀kùn, ó jáde lọ.
22
Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà.”
23
“Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù tuntun tàbí ọjọ́ ìsinmi.” Ó wí pé, “Gbogbo rẹ̀ ti dára.”
24
Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Máa nìṣó; má ṣe dẹ́sẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.”
25
Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Karmeli. Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi, “Wò ó! Ará Ṣunemu nì!
26
Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáradára? Ṣé ọkọ rẹ wà dáradára? Ṣé ọmọ rẹ wà dáradára?’ ” Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáradára.”
27
Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Gehasi wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú kíkorò, ṣùgbọ́n Olúwa fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.”
Settings