2 Ọba 15:10-14
10
Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀.
11
Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Sekariah. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.
12
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jehu jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”
13
Ṣallumu ọmọ Jabesi di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ussiah ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún oṣù kan.
14
Nígbà náà Menahemu ọmọ Gadi lọ láti Tirsa sí Samaria. Ó dojúkọ Ṣallumu ọmọ Jabesi ní Samaria, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Settings