2 Kronika 17:3-9
3
Olúwa sì wà pẹ̀lú Jehoṣafati nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dafidi ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Baali.
4
Ṣùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Israẹli.
5
Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
6
Ọkàn rẹ̀ sì gbé sókè si ọ̀nà Olúwa, pẹ̀lúpẹ̀lú, ó sì mú ibi gíga wọn àti ère òrìṣà Aṣerah kúrò ní Juda.
7
Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bene-Haili, Obadiah, Sekariah, Netaneli, Mikaiah láti máa kọ́ ni nínú ìlú Juda.
8
Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi, àní Ṣemaiah, Netaniah, Sebadiah, Asaheli, Ṣemiramotu, Jehonatani, Adonijah, Tobijah àti Tobu-Adonijah àti àwọn àlùfáà Eliṣama àti Jehoramu.
9
Wọ́n ń kọ́ ni ní agbègbè Juda, wọ́n mú ìwé òfin Olúwa wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Juda wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.
Settings